Oni iroyin: Poju Akintayo
Ijoba Ipinle Ogun, l’abe ase Gomina, Omooba Dapo Abiodun ti gbe ounte maajobalo le yiyan ti awon afobaje yan Omoba Afolabi Ogunlaja gegebi Nloku ti Ilu Iraye-Remo ni Ijoba Ibile Ariwa Remo no Ipinle naa.
Ni asiko kan na, Gomina Abiodun kede yiyan sipo awon Oba merin miran, n’igbati ijoba tun kede awon atúnṣe opopona meje kaakiri ipinle Ogun .
Awon ikede naa wa leyin ipade Igbimọ Alase ni Ipinle Ogun l’opin ose to pari yi. Ogunlogo iṣẹ akanṣe pataki ti Gomina gbe s’iwaju igbimo naa ni won ti di sise bayi.
N’igba ti igbimo n ye oro awon l’obal’oba tuntun wo, Omooba Raheem Afolabi Adimula Ogunlaja ni o le iwaju ijiroro won. Igbimo gba fifi Omooba Ogunlaja je Nloku ti Ilu Iraye-Remo w’ole Logan.
Ki a ma gbagbe pe Omooba Ogunlaja ni awon afobaje Ilu Iraye-Remo ati Ijoba Ibile Ariwa Remo ti yan lati d’ipo Oba Samuel Kalejaiye leyin ti Ile Ejo giga julo (Supreme Court) ti roo l’oye.
Awon Oba wonyi, Tajudeen Adeoye Olukunle, Onisale ti Isale, Gbokoto; Obajimi Sunday Olatunji, Alado of Ado, ni Sagamu; Dokita Adesegun Adedapo Ogunsola, Lowa Ibu ti Batoro, Sagamu; Alagba Moses Oludotun Fadairo, Baale ti Orile Oko, naa ri oju rere igbimo gba.
Àwọn ọ̀nà tí ipade bu onte otiseese lu je apá ọ̀tún oju ona Carwash si Moore Junction ni Abeokuta; lati Ojuiyipo titi oloda geere Molipa sí ibudoko Ibadan ni Ijebu-Ode; Opopona Ile-ẹkọ giga imo Bibeli ti o wa ni Ota; opopona Ajaka ni’yeba oja Awolowo ni Sagamu; opopona Gbadebo ni Ayegbami, Sagamu; opopona Okenla, Imoru Road ni Ijebu-Ode ati opopona Yemogun ni Ogere;
